The Noble Qur'an Encyclopedia
Towards providing reliable exegeses and translations of the meanings of the Noble Qur'an in the world languagesOriginator [Fatir] - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Ayah 18
Surah Originator [Fatir] Ayah 45 Location Maccah Number 35
وَلَا تَزِرُ وَازِرَةٞ وِزۡرَ أُخۡرَىٰۚ وَإِن تَدۡعُ مُثۡقَلَةٌ إِلَىٰ حِمۡلِهَا لَا يُحۡمَلۡ مِنۡهُ شَيۡءٞ وَلَوۡ كَانَ ذَا قُرۡبَىٰٓۗ إِنَّمَا تُنذِرُ ٱلَّذِينَ يَخۡشَوۡنَ رَبَّهُم بِٱلۡغَيۡبِ وَأَقَامُواْ ٱلصَّلَوٰةَۚ وَمَن تَزَكَّىٰ فَإِنَّمَا يَتَزَكَّىٰ لِنَفۡسِهِۦۚ وَإِلَى ٱللَّهِ ٱلۡمَصِيرُ [١٨]
Ẹlẹ́rù ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. Kódà kí ẹnì kan tí ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀ lọ́rùn ké sí (ẹlòmíìràn) fún àbárù ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, wọn kò níí bá a ru kiní kan nínú rẹ̀, ìbáà jẹ́ alábàátan ló ké sí.[1] Àwọn tí ò ń ṣèkìlọ̀ fún ni àwọn tó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀, tí wọ́n sì ń kírun. Ẹni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀), ó ṣàfọ̀mọ́ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.