The Noble Qur'an Encyclopedia
Towards providing reliable exegeses and translations of the meanings of the Noble Qur'an in the world languagesThe Table Spread [Al-Maeda] - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Ayah 72
Surah The Table Spread [Al-Maeda] Ayah 120 Location Madanah Number 5
لَقَدۡ كَفَرَ ٱلَّذِينَ قَالُوٓاْ إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡمَسِيحُ ٱبۡنُ مَرۡيَمَۖ وَقَالَ ٱلۡمَسِيحُ يَٰبَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ رَبِّي وَرَبَّكُمۡۖ إِنَّهُۥ مَن يُشۡرِكۡ بِٱللَّهِ فَقَدۡ حَرَّمَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِ ٱلۡجَنَّةَ وَمَأۡوَىٰهُ ٱلنَّارُۖ وَمَا لِلظَّٰلِمِينَ مِنۡ أَنصَارٖ [٧٢]
Wọ́n kúkú ti di kèfèrí, àwọn tó wí pé: “Dájúdájú Allāhu, Òun ni Mọsīh ọmọ Mọryam.” Mọsīh sì sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, ẹ jọ́sìn fún Allāhu, Olúwa mi àti Olúwa yín. Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá bá Allāhu wá akẹgbẹ́, Allāhu ti ṣe Ọgbà Ìdẹ̀ra ní èèwọ̀ fún un. Iná sì ni ibùgbé rẹ̀. Kò sì níí sí alárànṣe kan fún àwọn alábòsí.”